-
Òwe (Proverb): Ìyà méjì kìí jẹ òkóbó; tí ò bá lókó, á lóko
-
Igi gogoro má gún mi lójú; òkèèrè lati ń lọ̀ọ́
-
Òwe Ep2 (Ẹlédẹ̀ mi a dọ́ọ̀yọ́...)
-
Òwe Ep1 (Bi ọmọdé bá lásọ bí àgbà...)
-
A kìí bọ́ sínú omi tán ká máa kí gbe òtútù
-
A kìí dá aró ní Ìṣokùn. àla là ń wọ̀
-
A bímọ kò gbọ́n, a ní kó má ṣáà kú; kí ní ńpa ọmọ bí àigbọ́n?
-
A ríi lójú, a mọ̀ọ́ lẹ́nu, òṣòwò ọṣẹ kìí pọ́nwọ́lá
-
Ìpàkọ́ oní pàkọ́ làárí, ẹni ẹlẹ́ni ní rí tẹni
-
Ìjàkùmọ̀ kìí rìnde ọ̀sán, ẹni abíire kìí rìnde òru
-
A kìí gbódò jiyàn ọṣẹ́ hó tàbí kò hó
-
Àṣẹ̀ṣẹ̀ wọ́n ológbò ní jìyà, bó pẹ́ títi átéku ú pa.
-
Abayéjẹ kìí ṣe é fi ìdí ọ̀rọ̀ han
-
A kìí móko mẹ́jọ́ kọ̀kan máyẹ̀
-
Òní mò ń lọ, ọ̀la mò ń lọ, tí kìí jẹ́ kí àlejò gbin awùsá.
-
Ilé olóore kìí jó tan, tìkà kìí jó kù.
-
A kìí gbé ẹran erin lérí ká máa fẹsè wa iwò ìrẹ̀
-
K'ọ́ba ó gbó; k'ọ́ba ó tọ́ orí ahọ́n ní ń gbé- kòbákùngbé ọ̀rọ̀ ń bẹ lódò ikùn.
-
Ebí ń pamí, ọlọ́ṣẹ ń kiri, bi mi ò bá wẹnú, báwo ni n o ṣe wẹ̀de
-
igi ti a fẹyin ti, ti ò gbani dúró, ti o bá wó luni kò lè pani
-
À ń fọ̀tún tẹ́ní, à ń fòsì bọ́ ṣòkòtò, òbìrin ni a ò bá òun gbọ́ tọmọ